B'ọmọ bá t'ọkọ ní ò, à fún l'ọkọ Ṣèbí iyẹn ọmọ t'ó mọ'kọ' lò l'à ńwí Ọmọ t'á ò kọ', ìyẹn á kó ti'lé tà, pátá-pátá o B'ó bá wá tà iyẹn tán, á tún bọ' s'óko Á t'oko, á ta'lẹ, á t'omi, á t'odò Á ta bàbá, ta yèyé, ta gbogbo ẹbí rẹ' pátá Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, ọrẹ ò, ni wọn ńké Ẹ w'ẹ'sín wọn ní'ta, o jàre Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, awe ò, ni wọn ńké Ẹ w'ẹ'sín wọn ní'ta, o jàre Agẹmọ ti bí'mọ rẹ', ó bí'mọ rẹ' sí'nú ẹwà Àìmọ'ọ'jó ìyẹn wá d'ọwọ ọmọ ò Ọmọ tí ò gbẹ'kọ', ìyẹn á k'àbámọ ní'wájú o L'ọjọ ìdààmú, á wá fa'jú roro A w'òkè, á wo'lẹ, á w'òtún, á w'òsì A wo bàbá, a wo yèyé, pè gbogbo ẹbí rẹ' s'ẹ'kún Ẹ ò r'áyé ún l'óde, ọ'rẹ' ò, l'ó nké Ẹ w'ẹ'sín ún ní'ta, o jàre Ẹ ò r'áyé ún l'óde, àwé ò, l'ó nké Ẹ w'ẹ'sín ún ní'ta, o jàre Àṣádànù l'ọmọde ńṣá 'kuta iwájú ilé bàbá rẹ o Bó bá pẹ', ilé wọn á d'ahoro ò Ọmọ t'á ò tọ', ìyẹn á kó ti'lé tà pátá-pátá o B'ó bá wá tà yẹn tán, á tún bọ s'óko Á t'oko, á ta'lẹ', á t'omi, á t'odò Á ta bàbá, ta yèyé, ta gbogbo ẹbí rẹ pátá Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, ọrẹ ò, ni wọn ńké Ẹ w'ẹ'sín wọn ní'ta, o jàre Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, àwé ò, ni wọn ńké Ẹ wẹ'sín wọn ní'ta, o jàre Ẹ ma bà wa tọ wọn o, e tọ wọn Ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ ní'wà, yea (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà) Ẹ ma bà wá kọ wọn o, ẹ kọ wọn o Ẹ jọwọ, e tọ'mọ sọ'nà, ah (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ́nà) Ẹ má bà wá tọ wọn o, ẹ tọ wọn Ẹ jọwọ, ẹ kọ'wọn ní'wà (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà) Ẹ má kọ wọn o, ẹ kọ wọn Ẹ jọwọ, ẹ tọ wọn sọ'nà ah (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà) Ẹ ma bà wa tọ wọn o, ẹ tọ wọn Ẹ jọwọ, ẹ kọ wọn ní'wà (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà) Ẹ'jẹ' a má kọ wọn o, ẹ kọ wọn Ẹ jọ'wọ', ẹ tọ wọn sọ́nà, ah (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà) Àní, ẹ tọ wọn o, ẹ tọ wọn Ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ ní'wà, yeah (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà) Ẹ má bà wá kọ wọn o, ẹ ko wọn Ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà o (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà)